Ati ninu igbẹkẹle yi ni mo ti ngbèro ati tọ̀ nyin wá niṣãjú, ki ẹnyin ki o le ni ayọ nigbakeji; Ati lati kọja lọdọ nyin lọ si Makedonia, ati lati tún wá sọdọ nyin lati Makedonia, ati lati mu mi lati ọdọ nyin lọ si Judea. Nitorina nigbati emi ngbèro bẹ̃, emi ha ṣiyemeji bi? tabi ohun wọnni ti mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹgẹ bi ti ara bi, pe ki o jẹ bẹ̃ni, bẹ̃ni, ati bẹ̃kọ, bẹ̃kọ lọdọ mi? Ṣugbọn bi Ọlọrun ti jẹ olõtọ, ọ̀rọ wa fun nyin kì iṣe bẹ̃ni ati bẹ̃kọ. Nitoripe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, ẹniti a ti wasu rẹ̀ larin nyin nipasẹ wa, ani nipasẹ emi ati Silfanu ati Timotiu, kì iṣe bẹ̃ni ati bẹ̃kọ, ṣugbọn ninu rẹ̀ ni bẹ̃ni. Nitoripe bi o ti wu ki ileri Ọlọrun pọ̀ to, ninu rẹ̀ ni bẹ̃ni: ati ninu rẹ̀ pẹlu ni Amin, si ogo Ọlọrun nipasẹ wa.
Kà II. Kor 1
Feti si II. Kor 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 1:15-20
5 Days
In this journey through the Book of 2 Corinthians, All Things New explores Paul's theology of adventurous faith in this world and God's call for us to be bold. Kelly Minter helps us understand how the Christian walk may seem contrary to our natural tendencies, but it proves to be infinitely and eternally better. In this 5-day reading plan, you'll explore issues such as: how to deal with difficult relationships, trusting God with your reputation, grounding your identity in Christ, understanding the purpose of suffering and God's provision in it, and how we are to be gospel lights in the world.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò