II. Kor 1:1-4

II. Kor 1:1-4 YBCV

PAULU Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Timotiu arakunrin wa, si ijọ Ọlọrun ti o wà ni Korinti, pẹlu, gbogbo awọn enia mimọ́ ti o wà ni gbogbo Akaia: Õre-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa. Olubukún li Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba iyọ́nu, ati Ọlọrun itunu gbogbo; Ẹniti ntù wa ninu ni gbogbo wahalà wa, nipa itunu na ti a fi ntù awa tikarawa ninu lati ọdọ Ọlọrun wá, ki awa ki o le mã tù awọn ti o wà ninu wahala-ki-wahala ninu.