II. Kro 6:26-27

II. Kro 6:26-27 YBCV

Nigbati a ba se ọrun mọ́ ti kò si sí òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ; ṣugbọn bi nwọn ba gbadura si ibi yi, ti nwọn ba jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nitoriti iwọ pọn wọn loju. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ ji, ati ti Israeli enia rẹ, nigbati iwọ ba ti kọ́ wọn li ọ̀na rere na, ninu eyiti nwọn o ma rìn: ki o si rọ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun awọn enia rẹ ni ini.