Nigbana ni ọba ranṣẹ, nwọn si kó gbogbo awọn àgba Juda ati Jerusalemu jọ. Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo ọkunrin Juda, ati awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo enia ati ẹni-nla ati ẹni-kekere: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn. Ọba si duro ni ipò rẹ̀, o si dá majẹmu niwaju Oluwa lati ma fi gbogbo aiya ati gbogbo ọkàn rìn tọ̀ Oluwa lẹhin, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati ẹri rẹ̀, ati aṣẹ rẹ̀, lati ṣe ọ̀rọ majẹmu na ti a kọ sinu iwe yi.
Kà II. Kro 34
Feti si II. Kro 34
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kro 34:29-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò