II. Kro 30:6-9

II. Kro 30:6-9 YBCV

Bẹ̃li awọn onṣẹ ti nsare lọ pẹlu iwe lati ọwọ ọba ati awọn ijoye rẹ̀ si gbogbo Israeli ati Juda; ati gẹgẹ bi aṣẹ ọba, wipe, Ẹnyin ọmọ Israeli, ẹ tun yipada si Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, On o si yipada si awọn iyokù ninu nyin, ti o sala kuro lọwọ awọn ọba Assiria. Ki ẹnyin ki o má si ṣe dabi awọn baba nyin, ati bi awọn arakunrin nyin, ti o dẹṣẹ si Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn, nitorina li o ṣe fi wọn fun idahoro, bi ẹnyin ti ri. Njẹ ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọlọrùn lile, bi awọn baba nyin, ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Oluwa, ki ẹ si wọ̀ inu ibi-mimọ́ rẹ̀ lọ, ti on ti yà si mimọ́ titi lai: ki ẹ si sin Oluwa, Ọlọrun nyin, ki imuna ibinu rẹ̀ ki o le yipada kuro li ọdọ nyin. Nitori bi ẹnyin ba tun yipada si Oluwa, awọn arakunrin nyin, ati awọn ọmọ nyin, yio ri ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni ìgbekun lọ, ki nwọn ki o le tun pada wá si ilẹ yi: nitori Oluwa Ọlọrun nyin, oniyọ́nu ati alãnu ni, kì yio si yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ nyin, bi ẹnyin ba pada sọdọ rẹ̀.