ẸNI ọdun mẹdọgbọn ni Hesekiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba fun ọdun mọkandilọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Abijah, ọmọbinrin Sekariah. O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi, baba rẹ̀, ti ṣe. Li ọdun kini ijọba rẹ̀ li oṣù kini, o ṣí ilẹkun ile Oluwa, o si tun wọn ṣe. O si mu awọn alufa wá ati awọn ọmọ Lefi, o si kó wọn jọ si ita ila-õrun. O si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ọmọ Lefi; ẹ yà ara nyin si mimọ́ nisisiyi, ki ẹ si yà ile Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin si mimọ́, ki ẹ si kó ohun aimọ́ na jade kuro ni ibi mimọ́.
Kà II. Kro 29
Feti si II. Kro 29
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kro 29:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò