II. Kro 28:16-19

II. Kro 28:16-19 YBCV

Li akokò na ni Ahasi ọba, ranṣẹ si awọn ọba Assiria lati ràn on lọwọ. Awọn ara Edomu si tun wá, nwọn si kọlù Juda, nwọn si kó igbekun diẹ lọ. Awọn ara Filistia pẹlu ti gbé ogun lọ si ilu pẹtẹlẹ wọnni, ati siha gusu Juda, nwọn si ti gbà Bet-ṣemeṣi, ati Ajaloni, ati Gederoti, ati Ṣoko pẹlu ileto rẹ̀, Timna pẹlu ileto rẹ̀, ati Gimso pẹlu ati ileto rẹ̀: nwọn si ngbe ibẹ. Nitoriti Oluwa ti rẹ̀ Juda silẹ nitori Ahasi, ọba Juda: nitoriti o mu Juda di alaini iranlọwọ, o si ṣe irekọja gidigidi si Oluwa.