Ati lẹhin eyi ni Jehoṣafati, ọba Juda, dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Ahasiah, ọba Israeli, ẹniti o ṣe buburu gidigidi: O si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ ọ lati kan ọkọ̀ lati lọ si Tarṣiṣi: nwọn si kàn ọkọ̀ ni Esion-Geberi. Nigbana ni Elieseri ọmọ Dodafah ti Mareṣa sọtẹlẹ si Jehoṣafati wipe, Nitori ti iwọ ti dá ara rẹ pọ̀ mọ Ahasiah, Oluwa ti ba iṣẹ rẹ jẹ. Awọn ọkọ̀ na si fọ́, nwọn kò si le lọ si Tarṣiṣi.
Kà II. Kro 20
Feti si II. Kro 20
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kro 20:35-37
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò