II. Kro 20:20-23

II. Kro 20:20-23 YBCV

Nwọn si dide ni kutukutu owurọ, nwọn si jade lọ si aginju Tekoa: bi nwọn si ti jade lọ, Jehoṣafati duro, o si wipe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ará Juda, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu. Ẹ gbà Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́, bẹ̃li a o fi ẹsẹ nyin mulẹ; ẹ gbà awọn woli rẹ̀ gbọ́, bẹ̃li ẹnyin o ṣe rere. O si ba awọn enia na gbero, o yàn awọn akọrin si Oluwa, ti yio ma yìn ẹwa ìwa-mimọ́ bi nwọn ti njade lọ niwaju ogun na, ati lati ma wipe, Ẹ yìn Oluwa: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. Nigbati nwọn bẹ̀rẹ si ikọrin ati si iyìn, Oluwa yàn ogun-ẹhin si awọn ọmọ Ammoni, Moabu ati awọn ara òke Seiri, ti o wá si Juda, a si kọlù wọn. Awọn ọmọ Ammoni ati Moabu si dide si awọn ti ngbe òke Seiri, lati pa, ati lati run wọn tũtu: nigbati nwọn si pa awọn ti ngbe òke Seiri run tan, ẹnikini nṣe iranlọwọ lati run ẹnikeji.