Si kiyesi i, bi nwọn ti san a pada fun wa; lati wá le wa jade kuro ninu ini rẹ, ti iwọ ti fi fun wa lati ni. Ọlọrun wa! Iwọ kì o ha da wọn lẹjọ? nitori awa kò li agbara niwaju ọ̀pọlọpọ nla yi, ti mbọ̀ wá ba wa; awa kò si mọ̀ eyi ti awa o ṣe: ṣugbọn oju wa mbẹ lara rẹ. Gbogbo Juda si duro niwaju Oluwa, pẹlu awọn ọmọ wẹrẹ wọn, obinrin wọn, ati ọmọ wọn. Ṣugbọn lori Jahasieli, ọmọ Sekariah, ọmọ Benaiah, ọmọ Jeieli, ọmọ Mattaniah, ọmọ Lefi kan ninu awọn ọmọ Asafu, ni ẹmi Oluwa wá li ãrin apejọ enia na. O si wipe, Ẹ tẹti silẹ, gbogbo Judah, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu, ati iwọ Jehoṣafati ọba; Bayi li Oluwa wi fun nyin, Ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya nitori ọ̀pọlọpọ enia yi; nitori ogun na kì iṣe ti nyin bikòṣe ti Ọlọrun.
Kà II. Kro 20
Feti si II. Kro 20
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kro 20:11-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò