O si paṣẹ fun Juda lati ma wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, ati lati ma pa aṣẹ ati ofin rẹ̀ mọ́. O si mu ibi giga wọnni ati ọwọ̀n-õrun wọnni kuro lati inu gbogbo ilu Juda: ijọba na si wà li alafia niwaju rẹ̀. O si kọ́ ilu olodi wọnni ni Juda, nitoriti ilẹ na ni isimi, on kò si ni ogun li ọdun wọnni; nitori Oluwa ti fun wọn ni isimi. O si sọ fun Juda pe, Ẹ jẹ ki a kọ́ ilu wọnni, ki a si mọdi yi wọn ka, ati ile-iṣọ, ilẹkun ati ọpa-idabu, nigbati ilẹ na si wà niwaju wa, nitori ti awa ti wá Oluwa Ọlọrun wa, awa ti wá a, on si ti fun wa ni isimi yikakiri. Bẹ̃ni nwọn kọ́ wọn, nwọn si ṣe rere.
Kà II. Kro 14
Feti si II. Kro 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kro 14:4-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò