I. Tim 6:6-9

I. Tim 6:6-9 YBCV

Ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn ère nla ni. Nitori a kò mu ohun kan wá si aiye, bẹni a kò si le mu ohunkohun jade lọ. Bi a ba si li onjẹ ati aṣọ ìwọnyi yio tẹ́ wa lọrùn. Ṣugbọn awọn ti nfẹ di ọlọrọ̀ a mã bọ́ sinu idanwò ati idẹkun, ati sinu wère ifẹkufẹ pipọ ti ipa-ni-lara, iru eyiti imã rì enia sinu iparun ati ègbé.