I. Tim 5:3-16

I. Tim 5:3-16 YBCV

Bọ̀wọ fun awọn opó ti iṣe opó nitõtọ. Ṣugbọn bi opó kan ba li ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, jẹ ki nwọn tète kọ́ ati ṣe itọju ile awọn tikarawọn, ki nwọn ki o si san õre awọn obi wọn pada: nitoripe eyi li o ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun. Njẹ ẹniti iṣe opó nitõtọ, ti o ṣe on nikan, a mã gbẹkẹle Ọlọrun, a si mã duro ninu ẹ̀bẹ ati ninu adura lọsán ati loru. Ṣugbọn ẹniti o ba fi ara rẹ̀ fun aiye jijẹ, o kú nigbati o wà lãye. Nkan wọnyi ni ki iwọ ki o si mã palaṣẹ, ki nwọn ki o le wà lailẹgan. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò bá pèse fun awọn tirẹ, papa fun awọn ará ile rẹ̀, o ti sẹ́ igbagbọ́, o buru ju alaigbagbọ́ lọ. Máṣe kọ orukọ ẹniti o ba din ni ọgọta ọdún silẹ bi opó, ti o ti jẹ obinrin ọkọ kan, Ẹniti a jẹri rẹ̀ fun iṣẹ rere; bi o ba ti ntọ́ ọmọ ri, bi o ba ti ngba alejò, bi o bá ti nwẹ ẹsẹ awọn enia mimọ́, bi o ba ti nràn awọn olupọnju lọwọ, bi o ba ti nlepa iṣẹ rere gbogbo. Ṣugbọn kọ̀ awọn opo ti kò dagba: nitoripe nigbati nwọn ba ti ṣe ifẹkufẹ lodi si Kristi, nwọn a fẹ gbeyawo; Nwọn a di ẹlẹbi, nitoriti nwọn ti kọ̀ igbagbọ́ wọn iṣaju silẹ. Ati pẹlu nwọn nkọ́ lati ṣe ọlẹ, lati mã kiri lati ile de ile; ki iṣe ọlẹ nikan, ṣugbọn onisọkusọ ati olofòfo pẹlu, nwọn a ma sọ ohun ti kò yẹ. Nitorina mo fẹ ki awọn opo ti kò dagba mã gbeyawo, ki nwọn mã bímọ, ki nwọn ki o mã ṣe alabojuto ile, ki nwọn ki o máṣe fi àye silẹ rara fun ọtá na lati sọ̀rọ ẹ̀gan. Nitori awọn miran ti yipada kuro si ẹhin Satani. Bi obinrin kan ti o gbagbọ́ ba ni awọn opó, ki o mã ràn wọn lọwọ, ki a má si di ẹrù le ijọ, ki nwọn ki o le mã ràn awọn ti iṣe opó nitõtọ lọwọ.