I. Tim 5:21-22

I. Tim 5:21-22 YBCV

Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ati awọn angẹli ayanfẹ, ki iwọ ki o mã ṣakiyesi nkan wọnyi, laiṣe ojuṣãju, lai fi ègbè ṣe ohunkohun. Máṣe fi ikanju gbe ọwọ́ le ẹnikẹni, bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ alabapin ninu ẹ̀ṣẹ̀ awọn ẹlomiran: pa ara rẹ mọ́ ni ìwa funfun.