I. Tim 5:1-8

I. Tim 5:1-8 YBCV

MÁṢE ba alàgba wi, ṣugbọn ki o mã gba a niyanju bi baba; awọn ọdọmọkunrin bi arakunrin; Awọn àgba obinrin bi iya; awọn ọdọmọbirin bi arabinrin ninu ìwa mimọ́. Bọ̀wọ fun awọn opó ti iṣe opó nitõtọ. Ṣugbọn bi opó kan ba li ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, jẹ ki nwọn tète kọ́ ati ṣe itọju ile awọn tikarawọn, ki nwọn ki o si san õre awọn obi wọn pada: nitoripe eyi li o ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun. Njẹ ẹniti iṣe opó nitõtọ, ti o ṣe on nikan, a mã gbẹkẹle Ọlọrun, a si mã duro ninu ẹ̀bẹ ati ninu adura lọsán ati loru. Ṣugbọn ẹniti o ba fi ara rẹ̀ fun aiye jijẹ, o kú nigbati o wà lãye. Nkan wọnyi ni ki iwọ ki o si mã palaṣẹ, ki nwọn ki o le wà lailẹgan. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò bá pèse fun awọn tirẹ, papa fun awọn ará ile rẹ̀, o ti sẹ́ igbagbọ́, o buru ju alaigbagbọ́ lọ.