I. Tim 4:11-14

I. Tim 4:11-14 YBCV

Nkan wọnyi ni ki o mã palaṣẹ ki o si mã kọ́ni. Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ewe rẹ; ṣugbọn ki iwọ ki o jẹ apẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ́, ninu ọ̀rọ, ninu ìwa hihu, ninu ifẹ, ninu ẹmí, ninu igbagbọ́, ninu ìwa mimọ́. Titi emi o fi de, mã tọju iwe kikà ati igbaniyanju ati ikọ́ni. Máṣe ainani ẹ̀bun ti mbẹ lara rẹ, eyiti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu ifọwọle awọn àgba.