I. Tim 3:6-8

I. Tim 3:6-8 YBCV

Ki o má jẹ ẹni titun, kí o má bã gbéraga, ki o si ṣubu sinu ẹbi Èṣu. O si yẹ kí o ni ẹri rere pẹlu lọdọ awọn ti mbẹ lode: kí o má ba bọ sinu ẹ̀gan ati sinu idẹkun Èṣu. Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn diakoni lati ni ìwa àgba, ki nwọn má jẹ ẹlẹnu meji, kì nwọn má fi ara wọn fun waini pupọ̀, ki nwọn má jẹ olojukokoro.