NITORINA mo gbà nyin niyanju ṣaju ohun gbogbo, pe ki a mã bẹ̀bẹ, ki a mã gbadura, ki a mã ṣìpẹ, ati ki a mã dupẹ nitori gbogbo enia; Fun awọn ọba, ati gbogbo awọn ti o wà ni ipo giga; ki a le mã lo aiye wa ni idakẹjẹ ati pẹlẹ ninu gbogbo ìwa-bi-Ọlọrun ati ìwa agbà. Nitori eyi dara o si ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun Olugbala wa; Ẹniti o nfẹ ki gbogbo enia ni igbala ki nwọn si wá sinu ìmọ otitọ. Nitori Ọlọrun kan ni mbẹ, Onilaja kan pẹlu larin Ọlọrun ati enia, on papa enia, ani Kristi Jesu; Ẹniti o fi ara rẹ̀ ṣe irapada fun gbogbo enia, ẹrí li akokò rẹ̀; Nitori eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, (otitọ li emi nsọ, emi kò ṣeke;) olukọ awọn Keferi ni igbagbọ́ ati otitọ.
Kà I. Tim 2
Feti si I. Tim 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Tim 2:1-7
21 Days
Learn how best to pray, both from the prayers of the faithful and from the words of Jesus Himself. Find encouragement to keep taking your requests to God every day, with persistence and patience. Explore examples of empty, self righteous prayers, balanced against the pure prayers of those with clean hearts. Pray constantly.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò