Mo dupẹ lọwọ Ẹniti o fun mi li agbara, ani Kristi Jesu Oluwa wa, nitoriti o kà mi si olõtọ ni yiyan mi si iṣẹ rẹ̀; Bi mo tilẹ jẹ asọ ọ̀rọ-odì lẹkan rí, ati oninunibini, ati elewu enia: ṣugbọn mo ri ãnu gbà, nitoriti mo ṣe e li aimọ̀ ninu aigbagbọ. Ore-ọfẹ Oluwa wa si pọ̀ rekọja pẹlu igbagbọ́ ati ifẹ, ti mbẹ ninu Kristi Jesu. Otitọ li ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà, pe Kristi Jesu wá si aiye lati gbà ẹlẹṣẹ là; ninu awọn ẹniti emi jẹ pàtaki. Ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe ri ãnu gbà, pe lara mi, bi olori, ni ki Jesu Kristi fi gbogbo ipamọra rẹ̀ hàn bi apẹrẹ fun awọn ti yio gbà a gbọ́ si ìye ainipẹkun nigba ikẹhin. Njẹ fun Ọba aiyeraiye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọlá ati ogo wà fun lai ati lailai. Amin. Aṣẹ yi ni mo pa fun ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹgẹ bi isọtẹlẹ wọnni ti o ti ṣaju lori rẹ, pe nipa wọn ki iwọ ki o le mã jà ogun rere; Mã ni igbagbọ́ ati ẹri-ọkàn rere; eyiti awọn ẹlomiran tanu kuro lọdọ wọn ti nwọn si rì ọkọ̀ igbagbọ́ wọn: Ninu awọn ẹniti Himeneu ati Aleksanderu wà; awọn ti mo ti fi le Satani lọwọ, ki a le kọ́ wọn ki nwọn ki o má sọrọ-odi mọ́.
Kà I. Tim 1
Feti si I. Tim 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Tim 1:12-20
5 Days
Why was Jesus born? This may seem like a simple question, too familiar to ponder. But as you prepare for Christmas this year, take time to reflect on the deep meaning and purpose of Jesus's birth for your life, and for the whole world. This 5 day series was written by Scott Hoezee, and is an excerpt from the Words of Hope daily devotional.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò