I. Tes 5:9-11

I. Tes 5:9-11 YBCV

Nitori Ọlọrun yàn wa ki iṣe si ibinu, ṣugbọn si ati ni igbala nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o kú fun wa, pe bi a ba jí, tabi bi a ba sùn, ki a le jùmọ wà lãye pẹlu rẹ̀. Nitorina ẹ mã gbà ara nyin niyanju, ki ẹ si mã fi ẹsẹ ara nyin mulẹ, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe.