I. Tes 5:15-22

I. Tes 5:15-22 YBCV

Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia. Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo. Ẹ mã gbadura li aisimi. Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin. Ẹ máṣe pa iná Ẹmí. Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ. Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin. Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi.