I. Tes 5:14-18

I. Tes 5:14-18 YBCV

Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, ki ẹ mã kìlọ fun awọn ti iṣe alaigbọran, ẹ mã tù awọn alailọkàn ninu, ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ẹ mã mu sũru fun gbogbo enia. Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia. Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo. Ẹ mã gbadura li aisimi. Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin.