Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin; Ki ẹ si mã bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn. Ẹ si mã wà li alafia lãrin ara nyin. Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, ki ẹ mã kìlọ fun awọn ti iṣe alaigbọran, ẹ mã tù awọn alailọkàn ninu, ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ẹ mã mu sũru fun gbogbo enia. Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia. Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo. Ẹ mã gbadura li aisimi. Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin. Ẹ máṣe pa iná Ẹmí. Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ. Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin. Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi. Ki Ọlọrun alafia tikararẹ̀ ki o sọ nyin di mimọ́ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ́ patapata li ailabukù ni ìgba wíwa Oluwa wa Jesu Kristi. Olododo li ẹniti o pè nyin, ti yio si ṣe e.
Kà I. Tes 5
Feti si I. Tes 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Tes 5:12-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò