I. Tes 4:13-14

I. Tes 4:13-14 YBCV

Ṣugbọn awa kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ òpe, ará, niti awọn ti o sùn, pe ki ẹ má binujẹ gẹgẹ bi awọn iyoku ti kò ni ireti. Nitori bi awa ba gbagbọ́ pe Jesu ti kú, o si ti jinde, gẹgẹ bẹ̃ni Ọlọrun yio mu awọn ti o sùn pẹlu ninu Jesu wá pẹlu ara rẹ̀.