I. Sam 9:19-21

I. Sam 9:19-21 YBCV

Samueli da Saulu lohùn o si wipe, emi ni arina na: goke lọ siwaju mi ni ibi giga, ẹ o si ba mi jẹun loni, li owurọ̀ emi o si jẹ ki o lọ, gbogbo eyi ti o wà li ọkàn rẹ li emi o sọ fun ọ. Niti awọn kẹtẹkẹtẹ rẹ ti o ti nù lati iwọn ijọ mẹta wá, má fi ọkàn si wọn; nitoriti nwọn ti ri wọn. Si tani gbogbo ifẹ, Israeli wà? Ki iṣe si ọ ati si ile baba rẹ? Saulu si dahùn o si wipe, Ara Benjamini ki emi iṣe? kekere ninu ẹya Israeli? idile mi kò si rẹhìn ninu gbogbo ẹya Benjamini? ẽsi ti ṣe ti iwọ sọrọ yi si mi?