Dafidi si ba igba ọkunrin ti o ti rẹ̀ jù ati tọ̀ Dafidi lẹhin, ti on ti fi silẹ li odò Besori: nwọn si lọ ipade Dafidi, ati lati pade awọn enia ti o pẹlu rẹ̀: Dafidi si pade awọn enia na, o si ki wọn. Gbogbo awọn enia buburu ati awọn ọmọ Beliali ninu awọn ti o ba Dafidi lọ si dahun, nwọn si wipe, Bi nwọn kò ti ba wa lọ, a kì yio fi nkan kan fun wọn ninu ikogun ti awa rí gbà bikoṣe obinrin olukuluku wọn, ati ọmọ wọn; ki nwọn ki o si mu wọn, ki nwọn si ma lọ. Dafidi si wipe, Ẹ má ṣe bẹ̃, enyin ará mi: Oluwa li o fi nkan yi fun wa, on li o si pa wa mọ, on li o si fi ẹgbẹ-ogun ti o dide si wa le wa lọwọ. Tani yio gbọ́ ti nyin ninu ọ̀ran yi? ṣugbọn bi ipin ẹniti o sọkalẹ lọ si ìja ti ri, bẹ̃ni ipin ẹniti o duro ti ẹrù; nwọn o si pin i bakanna. Lati ọjọ na lọ, o si pa a li aṣẹ, o si sọ ọ li ofin fun Israeli titi di oni yi.
Kà I. Sam 30
Feti si I. Sam 30
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 30:21-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò