I. Sam 30:17-20

I. Sam 30:17-20 YBCV

Dafidi si pa wọn lati afẹmọjumọ titi o fi di aṣalẹ ijọ keji: kò si si ẹnikan ti o là ninu wọn, bikoṣe irinwo ọmọkunrin ti nwọn gun ibakasiẹ ti nwọn si sa. Dafidi si gba gbogbo nkan ti awọn ara Amaleki ti ko: Dafidi si gbà awọn obinrin rẹ̀ mejeji. Kò si si nkan ti o kù fun wọn, kekere tabi nla, ọmọkunrin tabi ọmọbinrin, tabi ikogun, tabi gbogbo nkan ti nwọn ti ko: Dafidi si gbà gbogbo wọn. Dafidi si ko gbogbo agutan, ati malu, nwọn si dà wọn ṣaju nkan miran ti nwọn gbà, nwọn si wipe, Eyiyi ni ikogun ti Dafidi.