I. Sam 26:15-16

I. Sam 26:15-16 YBCV

Dafidi si wi fun Abneri pe, Alagbara ọkunrin ki iwọ nṣe ndan? tali o si dabi iwọ ni Israeli? njẹ ẽṣe ti iwọ ko tọju ọba oluwa rẹ? nitori ẹnikan ninu awọn enia na ti wọle wá lati pa ọba oluwa rẹ. Nkan ti iwọ ṣe yi kò dara. Bi Oluwa ti mbẹ, o tọ ki ẹnyin ki o kú, nitoripe ẹnyin ko pa oluwa nyin mọ, ẹni-àmi-ororo Oluwa. Njẹ si wo ibiti ọ̀kọ ọba gbe wà, ati igò omi ti o ti wà nibi timtim rẹ̀.