I. Sam 25:35-37

I. Sam 25:35-37 YBCV

Bẹ̃ni Dafidi si gbà nkan ti o mu wá fun u li ọwọ́ rẹ̀, o si wi fun u pe, Goke lọ li alafia si ile rẹ, wõ, emi ti gbọ́ ohun rẹ, inu mi si dùn si ọ. Abigaili si tọ̀ Nabali wá, si wõ, on si se asè ni ile rẹ̀ gẹgẹ bi ase ọba; inu Nabali si dùn nitoripe, o ti mu ọti li amupara; on kò si sọ nkan fun u, diẹ tabi pupọ: titi di imọlẹ owurọ. O si ṣe; li owurọ, nigbati ọti na si dá tan li oju Nabali, obinrin rẹ̀ si rò nkan wọnni fun u, ọkàn rẹ̀ si kú ninu, on si dabi okuta.