I. Sam 23:14-18

I. Sam 23:14-18 YBCV

Dafidi si ngbe ni aginju, nibiti o ti sa pamọ si, o si ngbe nibi oke-nla kan li aginju Sifi. Saulu si nwá a lojojumọ, ṣugbọn Ọlọrun ko fi le e lọwọ. Dafidi si ri pe, Saulu ti jade lati wá ẹmi on kiri: Dafidi si wà li aginju Sifi ninu igbo kan. Jonatani ọmọ Saulu si dide, o si tọ Dafidi lọ ninu igbo na, o si gba a ni iyanju nipa ti Ọlọrun. On si wi fun u pe, Máṣe bẹru: nitori ọwọ́ Saulu baba mi kì yio tẹ̀ ọ: iwọ ni yio jọba lori Israeli, emi ni yio si ṣe ibikeji rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ̃ pẹlu. Awọn mejeji si ṣe adehun niwaju Oluwa; Dafidi si joko ninu igbo na. Jonatani si lọ si ile rẹ̀.