I. Sam 20:13-16

I. Sam 20:13-16 YBCV

Ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ si Jonatani: ṣugbọn bi o ba si ṣe pe o wu baba mi lati ṣe buburu si ọ, emi o si sọ ọ li eti rẹ, emi o si jẹ ki o lọ, iwọ o si lọ li alafia, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ gẹgẹ bi o ti wà pẹlu baba mi. Ki iṣe kiki igbà ti mo wà lãye ni iwọ o si ṣe ãnu Oluwa fun mi, ki emi ki o má kú. Ṣugbọn ki iwọ ki o máṣe mu ãnu rẹ kuro ni ile mi lailai: ki isi ṣe igbati Oluwa ke olukuluku ọtá Dafidi kuro lori ilẹ. Bẹ̃ ni Jonatani bá ile Dafidi da majẹmu wipe, Oluwa yio si bere rẹ̀ lọwọ awọn ọta Dafidi.