Bẹ̃ni Dafidi si fi kànakàna on okuta ṣẹgun Filistini na, o si bori Filistini na, o si pa a; ṣugbọn idà ko si lọwọ Dafidi. Dafidi si sure, o si duro lori Filistini na, o si mu ida rẹ̀, o si fà a yọ ninu akọ̀ rẹ̀, o si pa a, o si fi idà na bẹ́ ẹ li ori. Nigbati awọn Filistini si ri pe akikanju wọn kú, nwọn si sa. Awọn ọkunrin Israeli ati ti Juda si dide, nwọn si ho yè, nwọn si nle awọn Filistini lọ, titi nwọn fi de afonifoji kan, ati si ojubode Ekronu. Awọn ti o gbọgbẹ ninu awọn Filistini si ṣubu lulẹ li ọ̀na Ṣaaraimu, ati titi de Gati, ati Ekronu. Awọn ọmọ Israeli si pada lati ma lepa awọn Filistini, nwọn si ba budo wọn jẹ.
Kà I. Sam 17
Feti si I. Sam 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 17:50-53
5 Days
King David is described in the New Testament as a man after God’s own heart, meaning that he aligned his own heart with that of God’s. As we study David’s life, our goal for this series is to analyze the things David did in 1 & 2 Samuel in order to mold our hearts after God’s and resemble the same intensity of focus and spirit that David showcased throughout his life.
6 Awọn ọjọ
Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò