I. Sam 17:34-37

I. Sam 17:34-37 YBCV

Dafidi si wi fun Saulu pe, Nigbati iranṣẹ rẹ nṣọ agutan baba rẹ̀, kiniun kan si wá, ati amọtẹkun kan, o si gbe ọdọ agutan kan lati inu agbo. Mo si jade tọ̀ ọ, mo si lù u, mo si gbà a kuro li ẹnu rẹ̀: nigbati o si dide si mi, mo gbá irugbọ̀n rẹ̀ mu, mo si lù u, mo si pa a. Iranṣẹ rẹ pa ati kiniun ati amọtẹkun na: alaikọla Filistini yi yio si dabi ọkan ninu wọn, nitoripe on ti pe ogun Ọlọrun alãye ni ijà. Dafidi si wipe, Oluwa ti o gbà mi lọwọ́ kiniun ati lọwọ́ amọtẹkun, on na ni yio gbà mi lọwọ́ Filistini yi. Saulu si wi fun Dafidi pe, Lọ, Oluwa yio si pẹlu rẹ.