Bi on si ti mba wọn sọ̀rọ, sa wõ, akikanju ọkunrin na, Filistini ti Gati, ti orukọ rẹ̀ njẹ Goliati si goke wá, lati ogun awọn Filistini, o si sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ ti o ti nsọ ri: Dafidi si gbọ́. Gbogbo ọkunrin Israeli, nigbati nwọn si ri ọkunrin na, nwọn si sa niwaju rẹ̀, ẹ̀ru si ba wọn gidigidi. Awọn ọkunrin Israeli si wipe, Ẹnyin kò ri ọkunrin yi ti o goke wá ihin? lati pe Israeli ni ijà li o ṣe wá: yio si ṣe pe, ẹniti o ba pa ọkunrin na, ọba yio si fi ọrọ̀ pipọ fun u, yio si fun u li ọmọ rẹ̀ obinrin, yio si sọ ile baba rẹ di omnira ni Israeli. Dafidi si wi fun awọn ọkunrin ti o duro li ọdọ rẹ̀ pe, Kili a o ṣe fun ọkunrin na ti o ba pa Filistini yi, ti o si mu ẹgàn na kuro li ara Israeli? tali alaikọla Filistini yi iṣe, ti yio fi ma gan ogun Ọlọrun alãye? Awọn enia na si da a li ohùn gẹgẹ bi ọ̀rọ yi pe, Bayi ni nwọn o ṣe fun ọkunrin ti o ba pa a. Eliabu ẹgbọn rẹ̀ si gbọ́ nigbati on ba awọn ọkunrin na sọ̀rọ; Eliabu si binu si Dafidi, o si wipe, Ẽ ti ṣe ti iwọ fi sọkalẹ wá ihinyi, tani iwọ ha fi agutan diẹ nì le lọwọ́ li aginju? emi mọ̀ igberaga rẹ, ati buburu ọkàn rẹ; nitori lati ri ogun ni iwọ ṣe sọkalẹ wá. Dafidi si dahùn wipe, Kini mo ṣe nisisiyi? ko ha ni idi bi? On si yipada kuro lọdọ rẹ̀ si ẹlomiran, o si sọ bakanna: awọn enia na si fi esì fun u gegẹ bi ọ̀rọ iṣaju.
Kà I. Sam 17
Feti si I. Sam 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 17:23-30
5 Days
King David is described in the New Testament as a man after God’s own heart, meaning that he aligned his own heart with that of God’s. As we study David’s life, our goal for this series is to analyze the things David did in 1 & 2 Samuel in order to mold our hearts after God’s and resemble the same intensity of focus and spirit that David showcased throughout his life.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò