I. Sam 17:20-23

I. Sam 17:20-23 YBCV

Dafidi si dide ni kutukutu owurọ, o si fi agutan wọnni le olutọju kan lọwọ, o si mura, o si lọ, gẹgẹ bi Jesse ti fi aṣẹ fun u; on si de ibi yàra, ogun na si nlọ si oju ijà, nwọn hó iho ogun. Israeli ati Filistini si tẹgun, ogun si pade ogun. Dafidi si fi nkan ti o nmu lọ le ọkan ninu awọn olutọju nkan gbogbo lọwọ, o si sare si ogun, o tọ awọn ẹgbọn rẹ̀ lọ, o si ki wọn. Bi on si ti mba wọn sọ̀rọ, sa wõ, akikanju ọkunrin na, Filistini ti Gati, ti orukọ rẹ̀ njẹ Goliati si goke wá, lati ogun awọn Filistini, o si sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ ti o ti nsọ ri: Dafidi si gbọ́.