Samueli si sọ ìwa ijọba fun awọn enia na. O si kọ ọ sinu iwe, o si fi i siwaju Oluwa. Samueli si rán gbogbo enia na lọ, olukuluku si ile rẹ̀. Saulu pẹlu si lọ si ile rẹ̀ si Gibea; ẹgbẹ awọn alagbara ọkunrin si ba a lọ, ọkàn awọn ẹniti Ọlọrun tọ́. Ṣugbọn awọn ọmọ Beliali wipe, Ọkunrin yi yio ti ṣe gbà wa? Nwọn kẹgàn rẹ̀, nwọn ko si mu ọrẹ wá fun u. On si dakẹ.
Kà I. Sam 10
Feti si I. Sam 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 10:25-27
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò