I. Sam 1:26-28

I. Sam 1:26-28 YBCV

Hanna si wipe, oluwa mi, bi ọkàn rẹ ti wà lãye, oluwa mi, emi li obinrin na ti o duro li ẹba ọdọ rẹ nihin ti ntọrọ lọdọ Oluwa. Ọmọ yi ni mo ntọrọ; Oluwa si fi idahun ibere ti mo bere lọdọ rẹ̀ fun mi: Nitorina pẹlu emi fi i fun Oluwa; ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀: nitoriti mo ti bere rẹ̀ fun Oluwa. Nwọn si wolẹ-sin Oluwa nibẹ.