I. Pet 5:6-10

I. Pet 5:6-10 YBCV

Nitorina ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ labẹ ọwọ́ agbara Ọlọrun, ki on ki o le gbé nyin ga li akokò. Ẹ mã kó gbogbo aniyan nyin le e; nitoriti on nṣe itọju nyin. Ẹ mã wà li airekọja, ẹ mã ṣọra; nitori Èṣu, ọtá nyin, bi kiniun ti nke ramuramu, o nrìn kãkiri, o nwá ẹniti yio pajẹ kiri: Ẹniti ki ẹnyin ki o kọ oju ija si pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ́, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe ìya kanna ni awọn ara nyin ti mbẹ ninu aiye njẹ. Ọlọrun ore-ọfẹ gbogbo, ti o ti pè nyin sinu ogo rẹ̀ ti kò nipẹkun ninu Kristi Jesu, nigbati ẹnyin ba ti jìya diẹ, On tikarãrẹ, yio si ṣe nyin li aṣepé, yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, yio fun nyin li agbara, yio fi idi nyin kalẹ.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Pet 5:6-10