Nitoripe eyi ni ìtẹwọgba, bi enia ba fi ori tì ibanujẹ, ti o si njìya laitọ́, nitori ọkàn rere si Ọlọrun. Nitori ogo kili o jẹ, nigbati ẹ ba ṣẹ̀ ti a si lù nyin, bi ẹ ba fi sũru gbà a? ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣe rere; ti ẹ si njiya, bi ẹnyin ba fi sũru gbà a, eyi ni itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun. Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀: Ẹniti kò dẹṣẹ̀, bẹni a kò si ri arekereke lì ẹnu rẹ̀: Ẹni, nigbati a kẹgan rẹ̀, ti kò si pada kẹgan; nigbati o jìya, ti kò si kilọ; ṣugbọn o fi ọ̀ran rẹ̀ le ẹniti nṣe idajọ ododo lọwọ: Ẹniti on tikararẹ̀ fi ara rẹ̀ rù ẹ̀ṣẹ wa lori igi, pe ki awa ki o le di okú si ẹ̀ṣẹ ki a si di ãye si ododo: nipa ìnà ẹniti a mu nyin larada. Nitori ẹnyin ti nṣako lọ bi agutan, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin pada si ọdọ Oluṣọ-agutan ati Biṣopu ọkàn nyin.
Kà I. Pet 2
Feti si I. Pet 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Pet 2:19-25
5 Days
Repentance is one of the key actions we all take in coming to know Christ as our personal Savior. Repentance is our action and forgiveness is God's reaction to us out of His perfect love for us. During this 5-day reading plan, you will receive a daily Bible reading and a brief devotional designed to help you better understand the importance of repentance in our walk with Christ. For more content, check out www.finds.life.church
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò