I. Pet 2:18-20

I. Pet 2:18-20 YBCV

Ẹnyin ọmọ-ọ̀dọ, ẹ mã tẹriba fun awọn oluwa nyin pẹlu ìbẹru gbogbo; ki iṣe fun awọn ẹni rere ati oniwa tutu nikan, ṣugbọn fun awọn onrorò pẹlu. Nitoripe eyi ni ìtẹwọgba, bi enia ba fi ori tì ibanujẹ, ti o si njìya laitọ́, nitori ọkàn rere si Ọlọrun. Nitori ogo kili o jẹ, nigbati ẹ ba ṣẹ̀ ti a si lù nyin, bi ẹ ba fi sũru gbà a? ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣe rere; ti ẹ si njiya, bi ẹnyin ba fi sũru gbà a, eyi ni itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun.