I. Pet 1:18-21

I. Pet 1:18-21 YBCV

Niwọnbi ẹnyin ti mọ̀ pe, a kò fi ohun ti idibajẹ rà nyin pada, bi fadaka tabi wura, kuro ninu ìwa asan nyin, ti ẹnyin ti jogun lati ọdọ awọn baba nyin, Bikoṣe ẹ̀jẹ iyebiye, bi ti ọdọ-agutan ti kò li abuku, ti kò si li abawọn, ani ẹ̀jẹ Kristi; Ẹniti a ti mọ̀ tẹlẹ nitõtọ ṣaju ipilẹṣẹ aiye, ṣugbọn ti a fihan ni igba ikẹhin wọnyi nitori nyin, Ani ẹnyin ti o ti ipasẹ rẹ̀ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú, ti o si fi ogo fun u; ki igbagbọ́ ati ireti nyin ki o le wà lọdọ Ọlọrun.