I. Pet 1:15-25

I. Pet 1:15-25 YBCV

Ṣugbọn gẹgẹ bi Ẹni ti o pè nyin ti jẹ mimọ́, bẹ̃ni ki ẹnyin na si jẹ mimọ́ ninu ìwa nyin gbogbo: Nitori a ti kọ ọ pe, Ẹ jẹ mimọ́; nitoriti mo jẹ mimọ́. Bi ẹnyin ba si nkepè Baba, ẹniti nṣe idajọ gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku, li aiṣe ojuṣaju enia, ẹ mã lo igba atipo nyin ni ìbẹru: Niwọnbi ẹnyin ti mọ̀ pe, a kò fi ohun ti idibajẹ rà nyin pada, bi fadaka tabi wura, kuro ninu ìwa asan nyin, ti ẹnyin ti jogun lati ọdọ awọn baba nyin, Bikoṣe ẹ̀jẹ iyebiye, bi ti ọdọ-agutan ti kò li abuku, ti kò si li abawọn, ani ẹ̀jẹ Kristi; Ẹniti a ti mọ̀ tẹlẹ nitõtọ ṣaju ipilẹṣẹ aiye, ṣugbọn ti a fihan ni igba ikẹhin wọnyi nitori nyin, Ani ẹnyin ti o ti ipasẹ rẹ̀ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú, ti o si fi ogo fun u; ki igbagbọ́ ati ireti nyin ki o le wà lọdọ Ọlọrun. Niwọnbi ẹnyin ti wẹ̀ ọkàn nyin mọ́ nipa ìgbọran nyin si otitọ nipa Ẹmí si ifẹ ará ti kò li ẹ̀tan, ẹ fẹ ọmọnikeji nyin gidigidi lati ọkàn wá. Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro. Nitoripe gbogbo ẹran ara dabi koriko, ati gbogbo ogo rẹ̀ bi itanná koriko. Koriko a mã gbẹ, itanná rẹ̀ a si rẹ̀ silẹ: Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa duro titi lai. Ọ̀rọ yi na si ni ihinrere ti a wãsu fun nyin.