Ṣugbọn ọmọbinrin Farao goke lati ilu Dafidi wá si ile rẹ̀, ti Solomoni kọ́ fun u: nigbana ni o kọ́ Millo. Ati nigba mẹta li ọdun ni Solomoni iru ẹbọ ọrẹ-sisun, ati ẹbọ-ọpẹ lori pẹpẹ ti o tẹ́ fun Oluwa, o si sun turari lori eyi ti mbẹ niwaju Oluwa. Bẹ̃li o pari ile na. Solomoni ọba si sẹ ọ̀wọ-ọkọ̀ ni Esioni-Geberi, ti mbẹ li ẹba Eloti, leti Okun-pupa ni ilẹ Edomu. Hiramu si rán awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn atukọ ti o ni ìmọ okun, pẹlu awọn iranṣẹ Solomoni ninu ọ̀wọ-ọkọ̀ na. Nwọn si de Ofiri, nwọn si mu wura lati ibẹ wá, irinwo talenti o le ogun, nwọn si mu u fun Solomoni ọba wá.
Kà I. A. Ọba 9
Feti si I. A. Ọba 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. A. Ọba 9:24-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò