I. A. Ọba 22:51-53

I. A. Ọba 22:51-53 YBCV

Ahasiah, ọmọ Ahabu, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria li ọdun kẹtadilogun Jehoṣafati, ọba Juda, o si jọba li ọdun meji lori Israeli. O si ṣe ibi niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na baba rẹ̀, ati li ọ̀na iya rẹ̀, ati li ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o mu Israeli dẹ̀ṣẹ: Nitoriti o sin Baali, o si mbọ ọ, o si mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ ti ṣe.