Ati lẹhin isẹlẹ na, iná; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iná na, ati lẹhin iná na, ohùn kẹ́lẹ kekere. O si ṣe, nigbati Elijah gbọ́, o si fi agbáda rẹ̀ bo oju rẹ̀, o si jade lọ, o duro li ẹnu iho okuta na. Si kiyesi i, ohùn kan tọ̀ ọ wá wipe, Kini iwọ nṣe nihinyi Elijah? On si wipe, Ni jijowu, emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn si ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ; ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù; nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro. Oluwa si wi fun u pe, Lọ, pada li ọ̀na rẹ, kọja li aginju si Damasku: nigbati iwọ ba de ibẹ, ki o si fi ororo yan Hasaeli li ọba lori Siria. Ati Jehu, ọmọ Nimṣi ni iwọ o fi ororo yàn li ọba lori Israeli: ati Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ara Abel-Mehola ni iwọ o fi ororo yan ni woli ni ipò rẹ.
Kà I. A. Ọba 19
Feti si I. A. Ọba 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. A. Ọba 19:12-16
12 Days
Conversations With God is a joyous immersion into a more intimate prayer life, emphasizing practical ways to hear God's voice. God wants us to enjoy a running conversation with Him all of our lives—a conversation that makes all the difference in direction, relationships, and purpose. This plan is filled with transparent, personal stories about the reaching heart of God. He loves us!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò