I. A. Ọba 19:1-4

I. A. Ọba 19:1-4 YBCV

AHABU si sọ ohun gbogbo, ti Elijah ti ṣe, fun Jesebeli, ati pẹlu bi o ti fi idà pa gbogbo awọn woli. Nigbana ni Jesebeli rán onṣẹ kan si Elijah, wipe, Bẹ̃ni ki awọn òriṣa ki o ṣe si mi ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi emi kò ba ṣe ẹmi rẹ dabi ọkan ninu wọn ni iwoyi ọla. O si bẹ̀ru, o si dide, o si lọ fun ẹmi rẹ̀, o si de Beerṣeba ti Juda, o si fi ọmọ-ọdọ rẹ̀ silẹ nibẹ. Ṣugbọn on tikararẹ̀ lọ ni irin ọjọ kan si aginju, o si wá, o si joko labẹ igi juniperi kan, o si tọrọ fun ara rẹ̀ ki on ba le kú; o si wipe, O to; nisisiyi, Oluwa, gba ẹmi mi kuro nitori emi kò sàn jù awọn baba mi lọ!