I. A. Ọba 17:8-12

I. A. Ọba 17:8-12 YBCV

Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá wipe, Dide, lọ si Sarefati ti Sidoni, ki o si ma gbe ibẹ: kiyesi i, emi ti paṣẹ fun obinrin opó kan nibẹ lati ma bọ́ ọ. On si dide, o si lọ si Sarefati. Nigbati o si de ibode ilu na, kiyesi i, obinrin opó kan nṣa igi jọ nibẹ: o si ke si i, o si wipe, Jọ̃, bu omi diẹ fun mi wá ninu ohun-elo, ki emi ki o le mu. Bi o si ti nlọ bù u wá, o ke si i, o si wipe, Jọ̃, mu okele onjẹ diẹ fun mi wá lọwọ rẹ. On si wipe, Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, emi kò ni àkara, ṣugbọn ikunwọ iyẹfun ninu ìkoko, ati ororo diẹ ninu kòlobo: si kiyesi i, emi nṣa igi meji jọ, ki emi ki o le wọle lọ, ki emi ki o si peṣe rẹ̀ fun mi, ati fun ọmọ mi, ki awa le jẹ ẹ, ki a si kú.