O si ṣe li ọdun karun Rehoboamu ọba, Ṣiṣaki, ọba Egipti goke wá si Jerusalemu: O si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; ani gbogbo rẹ̀ li o kó lọ: o si kó gbogbo asà wura ti Solomoni ti ṣe lọ. Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn si ọwọ́ olori awọn oluṣọ ti nṣọ ilẹkun ile ọba. Bẹ̃li o si ri, nigbati ọba ba nlọ si ile Oluwa, nwọn a rù wọn, nwọn a si mu wọn pada sinu yara oluṣọ.
Kà I. A. Ọba 14
Feti si I. A. Ọba 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. A. Ọba 14:25-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò