I. A. Ọba 1:32-34

I. A. Ọba 1:32-34 YBCV

Dafidi ọba wipe, Ẹ pè Sadoku alufa fun mi, ati Natani woli, ati Benaiah ọmọ Jehoiada. Nwọn si wá siwaju ọba. Ọba si wi fun wọn pe, Ẹ mu awọn iranṣẹ oluwa nyin, ki ẹ si mu ki Solomoni ọmọ mi ki o gùn ibãka mi, ki ẹ si mu sọkalẹ wá si Gihoni. Ki ẹ si jẹ ki Sadoku, alufa, ati Natani woli, fi ororo yàn a nibẹ̀ li ọba lori Israeli: ki ẹ si fun fère, ki ẹ si wipe; Ki Solomoni ọba ki o pẹ!