I. Joh 4:9-14

I. Joh 4:9-14 YBCV

Nipa eyi li a gbé fi ifẹ Ọlọrun hàn ninu wa, nitoriti Ọlọrun rán Ọmọ bíbi rẹ̀ nikanṣoṣo si aiye, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀. Ninu eyi ni ifẹ wà, kì iṣe pe awa fẹ Ọlọrun, ṣugbọn on fẹ wa, o si rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa. Olufẹ, bi Ọlọrun ba fẹ wa bayi, o yẹ ki a fẹràn ara wa pẹlu. Ẹnikẹni kò ri Ọlọrun nigba kan ri. Bi awa ba fẹràn ara wa, Ọlọrun ngbé inu wa, a si mu ifẹ rẹ̀ pé ninu wa. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa ngbé inu rẹ̀, ati on ninu wa, nitoriti o ti fi Ẹmí rẹ̀ fun wa. Awa ti ri, a si jẹri, pe Baba rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ́ Olugbala fun araiye.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Joh 4:9-14